Ọkò ojú omi lebute, dúró díè, béè ló tèsíwájú Àmó, báféfé ti sowó òdì tó, wón padà dé Béè lèmi náà yóò dé léyìn osù méfà Ti n o tún gbéra fósù méfà mìíràn Gbogbo ènìyàn ló padà àfi àwon òré tòótó Béè làwon obìnrin olùfokànsìn tó sòwón Gbogbo ènìyàn ló padà àyàfi àwon tí a nílò jùlo Èmi ò gba kádàrá gbó. Béè n ò gbara mi gbó pèlú Àmó mo ni lérò pé kò ní máa rí béè lo Èyí ló sokùnfà bí okò ojú omi se rìn Dájúdájú n ó padà wá. Pèlú àwon òré, pèlú òtún isé Béè ni n ó korin léyìn osù méfà
© Bunmi Olujinmi. Ìtumọ, 2015